HYMN 715

S. 230 7s 6s (FE 742)
“Ma lo l'afiafia" - Luku 7:50
Tune: A roko a furugbin



1.  JESU Olugbala wa 

     Awa fi iyin fun O

     Fun ‘dasi ati pamo Re 

     Lori wa lat’esi

     A tun pejo loni yi 

     lati yin oruko Kristi 

     Kerubu, Serafu

     Awa ns’ajodun wa 

     L’oni niwaju Re 

     Ogo, Iyin ola ni fun 

     Metalokan Iailai.


2.  Baba Mimo bukun wa 

     Ninu ajodun yi 

     Fi Emi Mimo Re fun wa 

     At’agbara Emi

     K’a le sin O ni Mimo 

     Gba wa lowo ese 

     Aiye, esu, idanwo 

     Fun wa ni isegun

     Ki ‘mole wa le ma tan 

     Bi ‘lu Iori oke

     E jek‘ajuba fun Jesu 

     Oba wa Olore.


3.  Enyin Om'ogun Krsiti 

     E ku ewu odun

     E fun ipe Odagutan

     Ti baba fi fun yin 

     Enyin ti e nfi suru

     Ru agbalebu yin

     E o si joba lailai 

     Nigba ‘ponju ba tan

     Ipe ‘kehin dun tan 

     Fun ldajo aiye 

     Onidajo araiye yo 

     Ogunwa lori ‘te.


4.  Opo elegbe wa ni 

     Ko ri ojo oni 

     Ninu idamu aiye yi 

     Opo ti sako lo

     Jesu npe l’ohun jeje 

     Pe “OMO’ ma sako 

     Pada omo imole 

     Sinu agbo Jesu

     E kede jake jado

     Fun awon keferi

     Pe, ojo Oluwa de tan 

     E ronupiwada.


5.  Olorun ni Eleda 

     Orun ati aiye

     O nfun itanna l’awo

     O nmu irawo tan

     Iji gba ohun re gbo 

     O nbo awon eiye 

     Papa awa omo Re 

     T'o nbo lojojumo

     Ebun rere gbogbo 

     Lati orun wa ni

     A dupe lowo Olorun 

     Fun gbogbo ife Re.


6.  Igba wa mbe l‘owo re 

     Nin’odun t’a wa yi 

     Om’ogun Kristi, e gbadura 

     Metalokan y’o gbo

     Iwo l'a nwo t’a si nsin 

     Ma jek’oju tiwa 

     Ma jeki’awa omo Re 

     Sokun ni ainidi

     Iwo la gbekele

     Iwo ni ‘reti wa

     Ran wa lowo k’a le sin O 

     De opin emi wa.  Amin

English »

Update Hymn