HYMN 711

(FE 738)
"Tani ki ba beru Re, Iwo Oba 
orile-ede" - Jer. 10:7
Tune: Lo kede ayo na fun gbogbo aiye



1.  E ku ewu odun, E ku ‘yedun 

     A s’ope fun Olorun wa,

     T’o mu wa ri ajodun oni yi 

     Ni orile aiye.

Egbe: Awa dupe a run ope da 

          Ogo, Ola at'Agbara ati'pa 

          F'Od'agutan t'o gunwa.


2.  Kristi se ‘mole at'alabo wa 

     M'ese agbo Re yi duro 

     Pese ise f’awon ti ko ri se 

     Se ‘wosan alaisan.

Egbe: Awa dupe...


3.  Oluwa ni Olus’Agutan mi

     Emi ki yio se alaini

     O mu mi dubule ni papa oko tutu 

     O tu okan mi l'ara.

Egbe: Awa dupe...


4.  Bi emi ba tile nrin koja lo 

     Larin afonifoju 'ku

     Emi ki o si beru ibi kan 

     Tori ‘Wo wa pelu mi.

Egbe: Awa dupe...


5.  Awon ogo Re ati opa Re 

     Awon ni o tu mi ninu

    O te tabil’ onje sile n’iwaju 

    L’oju awon ota mi.

Egbe: Awa dupe...


6.  Iwo da ororo si mi l’ori

     Ago mi k’ akun wo sile

     Ire, anu ni yio ma to mi lehin 

     L’ojo aiye mi gbogbo.

Egbe: Awa dupe...


7.  Kristi Olugbala awa mbe O 

     Jowo ran Emi Re si wa

     K’a le wo wa l’aso Ogo didan 

     Ni ikehin ojo aiye wa.

Egbe: Awa dupe...


8.  Kabiyesi, Oba Alaiyeluwa 

     Metalokan Aiyeraiye

     Fun wa n’isegun n’igba idanwo 

     K’owo esu ma te wa.

Egbe: Awa dupe...


9.  Baba oke orun awa mbe O 

     Sure fun wa k’a wa to lo 

     Jesu bebe fun awa omo Re 

     K’a le j’oba pelu Re.

Egbe: Awa dupe a run ope da 

          Ogo, Ola at'Agbara ati'pa 

          F'Od'agutan t'o gunwa.  Amin

English »

Update Hymn