HYMN 709

1.  A dupe Oluwa 

     F‘ajodun oni

     O da emi wa si 

     Ogo f’oko Re 

     Pelu orin ayo 

     L'a o fi josin

     Fun bukun aye wa 

     On reti orun. 

Egbe: Ajodun de, e yo

          Ke, AIeluya

          A m 'ore ope wa

         Tewo gb’ore wa.


2.  Opo l'elegbe wa 

     Ni ko tun si mo 

     Opo ti sako lo 

     Kuro lodo Krist 

     A dupe Oluwa 

     Pe O da wa si

     O si tun ka wa ye 

     F’ajodun oni. 

Egbe: Ajodun de, e yo...


3.  Baba wa li orun 

     Awa se pinu

     Pe ao sin Jesu 

     L'ojo aye wa

     A o sise fun dagba 

     Soke ijo wa

     Tit‘ ao fi je ‘pe Re 

     Fun ‘simi orun. 

Egbe: Ajodun de, e yo...


4.  Wo Oluw'ajodun 

     A f’ope fun O

     Je k’ire ajodun 

     kari gbogbo wa 

     A be O, Olorun

     Fun wa l’agbara

     Lati sin O d'opin 

     Ojo aye wa.

Egbe: Ajodun de, e yo

          Ke, AIeluya

          A m 'ore ope wa

         Tewo gb’ore wa.  Amin

English »

Update Hymn