HYMN 708

S.O. E.D 522 (FE 735) 
“Lojojumo Ii ao si ma yin I“ - Ps. 72:15 
Tune: Edumare Jah Jehovah



1.  BABA Orun wa gb’ope wa 

     Fun ajodun wa oni yi 

     Fun idasi at’abo Re

     To nfun wa lojojumo.

Egbe: Jehofa Jire

           Ran ibukun Re si wa 

           K’awa le se 'fe Re d’opin 

           Ko wa de Paradise.


2.  Olugbala wa gb’ope wa 

     T’isegun t’o nse fun wa 

     Gbat’esu nfe bi wa subu 

     Ti a si nri ‘ranwo Re.

Egbe: Jehofa Jire...


3.  Kerubu ati Serafu 

     E jek’a yin Baba wa
  
     Ti ko f’emi adaba Re 

     Fun eranko igbe je.

Egbe: Jehofa Jire...


4.  Jehofa Shammah mbe fun wa 

     T’o ran Maikaeli si wa

     Fun ‘segun wa l‘ona gbogbo 

     Iyin fun Metalokan.

Egbe: Jehofa Jire...


5.  Olupese wa y’o pese 

     Pese ‘se rere fun wa 

     Awon agan y’o bimo 

     Enit’ o bi a tunla.

Egbe: Jehofa Jire...


6.  Wa pelu Egbe Idale 

     Kerubu on Serafu

     Pese fun won l‘ona gbogbo 

     Baba wa ba won ‘segun.

Egbe: Jehofa Jire...


7.  A mbebe f'awon eda Re 

     T'o wa ni gbogbo aiye 

     K'a ronu pa iwa wa da 

     K’a le ye ‘bugbe orun.

Egbe: Jehofa Jire...


8.  Gbogbo enyin ero mimo 

     Ti Egbe Aladura

     E se ran nyin l‘okansoso 

     Gege bi Metalokan.

Egbe: Jehofa Jire...


9.  Orin Halle, Halleluyah, 

     Ni awa y’o ko l’orun 

     Nigbat‘ a ba de ‘te Baba 

     N’ile isura orun.

Egbe: Jehofa Jire

           Ran ibukun Re si wa 

           K’awa le se 'fe Re d’opin 

           Ko wa de Paradise.  Amin

English »

Update Hymn