HYMN 707

(FE 734)
Tune: E ti gbo orin ile wura na



1.  A KI nyin e ku ajodun oni 

     Enyin omo Egbe Serafu

     A dupe lowo Baba wa orun 

     T’o da wa si di oni.

Egbe: E ho iho ayo gbogbo Serafu 

          Fun ogun rere ti fun wa 

          Lat’owo Mose Orimolade 

          T'o d’Egbe Serafu s’aiye.


2.  Awon olufe wa ti goke lo 

     Nwon koja s’aiya baba wa 

     Nwon mboju wo wa lati oke na 

     Lati wo b‘a ti nsise.

Egbe: E ho iho ayo...


3.  Baba Aladura mura giri 

     Lati tele ona na

     Sise pelu gbogbo agbara Re 

     K‘egbe le tesiwaju.

Egbe: E ho iho ayo...


4.  Eni owo ‘tun Baba Aladura 

     Ogbeni Senior Apostle

     Ati gbogbo awon Apostle 

     E gbe iwo ‘gbagbo s’oke.

Egbe: E ho iho ayo...


5.  A ki nyin gbogbo enyin oloye 

     E ku ajodun oni yi

     L‘okunrin, l’obinrin

     K’a se ‘yi ka s’amodun.

Egbe: E ho iho ayo gbogbo Serafu 

          Fun ogun rere ti fun wa 

          Lat’owo Mose Orimolade 

          T'o d’Egbe Serafu s’aiye.  Amin

English »

Update Hymn