HYMN 706

(FE 733)
"E di amure yin” - Luku 12:35 
Tune: Oluwa fise ran mi Alleluya


1.  AWA l'omo ogun Kristi Alleluya

    T’Oluwa gbe dide funra Re 

    Awa nsajodun loni Alleluya 

    A dupe fun ‘dasi emi wa. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun Kristi 

          Korin soke s'Oba wa

          Ope ni fun Olugbala Alleluyah

          Fun idasi wa d’ojo loni.


2.  Gbogbo egbe Kaduna Alleluyah

     E f'ogo fun Baba wa l’oke 

     F’Egbe Omo-Ogun Kristi Alleluyah

     T’Oluwa gbe dide larin yin.

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


3.  Esu ma gbogun titi, Alleluyah 

     Lati b’egbe Mimo yi subu 

     Sugbon Jesu gbe wa ro Alleluyah

     Ogo ni fun Baba wa loke.

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


4.  Ope FOlugbala wa Alleluyah

     T‘o da wa si lati esi wa 

     Awa si ngbadura, Alleluyah 

     K‘a le se opolopo odun. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


5.  Jesu Olor'egbe wa, Alleluyah

     A f‘ogo f'oruko Mimo Re 

     Jowo di wa l’amure Alleluyah

     K'a le jagun b'omogun toto. 

Egbe: Damuso Omo-Ogun...


6.  Ki gbogbo egbe ho ye Alleluyah

     K’a f’ogo fun baba wa l’oke 

     K'a f‘ogo fun Omo Re

     K’a tun f’ogo fun Emi Mimo.

Egbe: Damuso Omo-Ogun Kristi 

          Korin soke s'Oba wa

          Ope ni fun Olugbala Alleluyah

          Fun idasi wa d’ojo loni.  Amin

English »

Update Hymn