HYMN 704

t. 8s 7s (FE 731)
"Iwo o pa mo li alafia" - Isaiah.26:3
Tune: Baba to da orun meje


1.  ALAFIA ni f‘Egbe na,

     T'o nse ajodun loni 

     Kerubu t’oke sokale 

     Lati ba wa yo ayo na. 

Egbe: Awa njo-awa nyo 

          Ogun orun sokale - 2ce


2.  Omo Egbe Kristi Mimo 

     E wa k’ajo y‘ayo na 

     K'enikeni ma ku sehin

     Gbogbo wa ni Jesu npe. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


3.  Egbe Kerubu Serafu 

     At‘awon aladura 

     At‘enyin onisin-owuro 

     Jek‘a korin na soke. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


4.  Egbe Mary, Egbe Martha 

     Egbe Ayaba Esther

     Egbe Dorcas gbohun soke 

     K'a jumo yo ayo na.

Egbe: Awa njo-awa nyo...


5.  Orin Halle,Halleluyah 

     L‘awa yio ma ko lorun 

     Gbat‘aba ri Olugbala 

     Lor'ite Baba loke. 

Egbe: Awa njo-awa nyo...


6.  Egbe Dafidi, Egbe Aaroni 

     Egbe F’Ogo Olorun han 

     Egbe Baba nla mejila 

     Gbe ‘da segun nyin soke.

Egbe: Awa njo-awa nyo...


7.  E f'Ogo fun Baba loke

     E f’Ogo fun Omo Re

     Ogo ni fun Emi Mimo

     Ope ye Metalokan.

Egbe: Awa njo-awa nyo 

          Ogun orun sokale

          Ogun orun sokale.  Amin

English »

Update Hymn