HYMN 701

8.7.8.7 D



1.  OLUWA, a gbe okan wa

     Si O n‘nu orin iyin

     A m’ore ope wa fun O 

     Pelu iho ayo nla 

     Gbogbo papa f'ewa bora 

     Awon oke nho f‘ayo 

     Oka po l’afonifoji

     Tobe ti won fi nkorin.


2.  Loni, ojo ikore wa 

     Awa jewo ore Re

     Awa f’ope mu ebun wa 

     Akoso ibukun Re

     Wo l’o nfi ore-ofe bo 

     Okan awa eda Re

     Wo ti npese onje ojo 

     Fi onje orun bo wa.


3.  A nfarada oru ojo 

    Laalaa a si ma su-ni 

    Sugbon nigbati oorun wo 

    Simi de fun alaare

    Se wa l’eni itwogba 

    Gbat‘ angeli ba nkore 

    K’a je alikama Kristi

    Ti On y‘o to si aba.


4.  lbukun n'ile Olorun 

     Bit‘ awon mimo wa lae 

     Papa wura teju ni be 

     Odo re ndan bi Kristal 

     Orin egbe mimo t'ohun 

     Dapo mo tiwa loni 

     Bukun orin kore na po 

     Ti a o ma ko titi.  Amin

English »

Update Hymn