HYMN 700

C.M.S 421.H.C 519 P.M (FE 727)
"Angeli Oluwa wipe, Lo so
gbogbo oro iye yi" - Ise. 5:20



1.  GBO, okan mi, bi Angeli ti nkorin 

     Yika orun ati yika aiye

     E gbo bi oro orin won ti dun to

     Ti nso gbati ese ki y’o si me.

Egbe: Angeli Jesu, angel'mole 

          Nwon nkorin ayo pade ero 

          Iona.


2.  B’a si ti nlo be l’a si ngbo orin won

     Wa alare, Jesu l’o ni k’e wa

     L’okunkun ni a ngbo orin didun won 

     Ohun orin won ni nfona han wa.

Egbe: Angeli Jesu...


3.  Ohun Jesu ni a ngbo l’ona rere 
 
     Ohun na ndun b’agogo y’aiye ka 

     Egbegberun awon t’o gbo ni si mbo 

     Mu won w’odo Re Olugbala wa. 

Egbe: Angeli Jesu...


4.  Isimi de, bi wahala tile po 

     Ile y’o mo, lehin okun aiye 

     Irin ajo pari f’awon alare

     Nwon o d’orun bi simi nikehin.

Egbe: Angeli Jesu...


5.  Ma korin nso, enyin Angeli rere 

     E ma korin didun k’a ba ma gbo 

     Tit’ ao fi nu omije oju wa nu;

     Ti ao si ma yo titi lailai.

Egbe: Angeli Jesu, angel'mole 

          Nwon nkorin ayo pade ero 

          Iona.  Amin

English »

Update Hymn