HYMN 699

(FE 725)
"Nitori ki yio si oru nibe" - Ifi. 21:25



1.  ILE kan mbe to dara julo 

     A le fi ‘gbagbo ri I’okere 

     Nitori Baba duro l'ona 

     Lati fi le kan fun wa nibe. 

Egbe:  Kerubu, Serafu

           E ho fun ayo lojo oni - 2ce


2.  Awa y’o korin l’ebute na 

     Orin didun awon t’a bukun 

     Okan wa ko ni banuje mo 

     Tori ayo ailopin wa n’be. 

Egbe:  Kerubu, Serafu...


3.  Baba wa Olore ni orun 

     Nikan n'iyin at’ope ye fun 

     Tori ebun ogo ife re

     Eyiti se Olugbala wa. 

Egbe:  Kerubu, Serafu...


4.  Tan mole Re si okunkun wa, 

     L’akoko t’egbe Serafu de

     Ki gbogbo aiye le yipada 

     Lati juba fun Kristi Oluwa.

Egbe:  Kerubu, Serafu...


5.  Gba t’a gbe ago erupe wo

     Ti ota ba fe se wa n’ibi 

     T’erokero ba fe gb’okan wa, 

     Ki Jehofa ko gbo ebe wa.

Egbe:  Kerubu, Serafu...


6.  Nigbat’ o ba d’ojo ikehin 

     Ti omo ko ni mo baba re 

     Ma je k’oju ti wa lojo na 

     Ki Metalokan tewo gba wa.

Egbe:  Kerubu, Serafu

           E ho fun ayo lojo oni - 2ce  Amin

English »

Update Hymn