HYMN 698

C.M.S 416 H.C 422 10
10.10 4 (FE 23) 
"A fi awosanma eleri pupo yi wa ka."
- Heb. 12:1



1.  F'AWON enia Re to lo simi

     Awon ti o f’igbagbo jewo Re,

     A yin oruko Re, Olugbala, 

     Helleluya!


2.  Iwo l’apata won at’odi won 

     Iwo ni Balogun won l'oju ‘ja, 

     Iwo ni imole okunkun won 

     Halleluya!


3.  Je ki awon omo-ogun Re laiye, 

     Jagun nitoto b‘awon ti ‘gbani

     Ki nwon le gba ade ogo bi won

     Halleluya!


4.  Idapo ibukun wo lo to yi

     Awa nja nihin, awon nyo lohun 

     Be Tire kanna l’awa at‘ awon 

     Halleluya!


5.  Gbat’ ija ngbona ti ogun nle 

     A dabi eni ngborin ayo won 

     Igboiya a si de at'agbara 

     Halleluya!


6.  Ojo nlo orun wa fere wo na 

     Awon ajagun toto y’o simi 

     Didun ni isimi Paradise 

     Halleluya!


7.  Lehin eyi ojo ayo kan mbo 

     Awon mimo yo jinde ninu Ogo 

    Oba ogo y‘o si wa larin won 

    Halleluya!


8.  Lat‘ opin ile lat’opin okun 

    Ogunlogo nro wo bode Pearli 

    Nwon nyin Baba, Omo ati Emi 

    Halleluya!  Amin

English »

Update Hymn