HYMN 697

H.C 513 8.9.8.8 (FE 722)
“Jeki oju Re si si ile yi”
- 1Oba 8:29
Tune: A nsoro ile bukun ni



1.  NIHIN l‘oruko Re Oluwa 

     A ko le erupe fun O

    Yan fun ‘bugbe Re pataki 

    K'o si so lowo ja esu.


2.  Gbati a ba ngbadura nihin 

     T’elese nbebe fun Iye 

     Gbo lati 'bugbe re orun 

     Gbat' o ba gbo k‘o dariji.


3.  Gbat;’ a nwasu Re nihin 

     Ninu ile Mimo Re yi 

     Nip‘ agbara Oko nla Re 

     K‘ise yanu re farahan.


4.  Gbat' awon ewe ba nkorin 

     Hosanna si Oba wa loke

     Ki ogo Re kun ile yi 

     K’Angeli ba won korin na.


5.  K'ogo Re ma gbe ile yi 

     Yan ni ile patapata

     Te ite Re sinu ‘le yi 

     Majeki esu le wo ‘be.


6.  Jah Jehofa, Oba Mimo 

     Sokale sinu okan wa

     Ma ba wa gbe inu ile wa 

     Mase fi wa sile lailai.  Amin

English »

Update Hymn