HYMN 696

(FE 721)
“Oluwa awon omo ogun gbo
adura mi." ‐ Ps. 84:8
Tune: T’Oluwa nile at’ekun re.



1.  OGUN Orun, e wa ba wa yo 

     Fun ile t’a nsi loni

     Awa be O Jesu baba wa 

     Ma sai bukun wa loni.

Egbe: Yala Eru l'o nkepe O 

           Tabi ominira, Baba 

           Ko gbo n'ile yi.


2.  Awa dupe lowo Re Baba 

     T’o mu ileri Re se 

     Baba se leri fun Kerubu 

     O mu se fun Serafu.

Egbe: Yala Eru...


3.  Baba se ‘leri fun Abraham 

     O mu se fun Isaaki

     Baba se ‘leri fun Dafidi

     O mu se fun Solomon.

Egbe: Yala Eru...


4.  Ogo ati Ola fun Baba 

     Ogo F'Omo Re pelu 

     Ogo ati ola fun Eni.

Egbe: Yala Eru l'o nkepe O 

           Tabi ominira, Baba 

           Ko gbo n'ile yi.  Amin

English »

Update Hymn