HYMN 691

C.M.S 576 H.C 378 6s 4s (FE 716) 
"Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile Re."
- Ps. 84 : 4



1.  KRISTI n’ipile wa 
 
     Lori Re lao kole 

     Awon Mimo nikan 

     L’o ngb’ agbala orun

     Ireti wa, T'ore aiye

     T’ayo ti mbo, Wa n‘nu fe Re.


2.  Agbala Mimo yi 

     Y’o ho f’orin iyin 

     A o korin iyin si 

    Metalokan Mimo,

    Be lao f’orin, Ayo kede 

    Oruko Re, Titi aiye.


3.  Olorun Olore 

     Fiyesini, nihin 

     Lati gba eje wa 

     At’ebe wa gbogbo

     K‘o si f’opo, Bukun dahun, 

     Adura wa, Nigbagbogbo.


4.  Nihin, je k’ore Re 

     T’a ntoro l’ at’orun 

     Bo sori wa lekan 
  
     K’o ma si tun lo mo

     Tit’ojo na, T‘ao s‘akojo 

     Awon Mimo Sib’isimi.  Amin

English »

Update Hymn