HYMN 689

H.C 177 t.S 43. P.M
"Nitorina a fi ipile re sole lori 
apata" - Matt 7:25



1.  IPILE TI JESU Fl LE‘LE L'EYI

     Ti Baba Aladura nto,

     K’eda mase ro pe

     O ye kuro nibe, O duro le Krist‘ apata. 

Egbe: Kerubu E yo, Serafu Eyo,

          A fi pile lele lori otito - 2ce


2.  Bi ara nsan egbagbeje ohun 

     Omo Jesu yio duro ti 

     K'enia ma kegan oko Noa 

     Oko refo omo Jesu la. 

Egbe: Kerubu E yo...


3.  A rojo mo Stephen , a ro ‘jo mo Peter 

     A rojo mo jesu Oluwa

     A rojo mo Mose Orimolade

     K’eda k‘o kiyes’ara.

Egbe: Kerubu E yo...


4.  Baba Aladura dide damure

     Lati pade awon Kerubu

     Olorun ti yin ise Re lat‘ oke wa, 

     Ade iye yio je tire. 

Egbe: Kerubu E yo...


5.  B'aiye mbu Mose,

     Awon Angeli nfe

     Olorun Abraham nfe

     Awon Ogun Orun si ngbadura re, 

     Olorun Metalokan.

Egbe: Kerubu E yo, Serafu Eyo,

          A fi pile lele lori otito

          A fi pile lele lori otito.  Amin

English »

Update Hymn