HYMN 688

C.M. (FE 713)
"Oluwa, ko mi Ii ona Re, emi o 
si ma pa mo de opin" - Ps. 119:33
“Apere Olorun mimo lati igba ewe.”



1.  WO awon apere wonni 

     Ti mbe n’nu Bibeli 

     T’awon t’o fe Isin Jesu 

     Lati ‘gba ewe won.


2.  Jesu, Oba l’oke orun 

     T‘ola Re kun aiye 

     Je omode bi emi ri

     O np’ ofin baba mo.


3.  Mejila pere l‘odun Re 

     Gb‘o ndamu awon Ju 

     Sugbon sibe, o teriba 

     O si gbo t’iya Re.


4.  B'awon agba ti nkegan to 

     Ti nwon ns’abuku Re

     Be l‘awon ewe nyin logo 

     Ti nwon nke Hosanna!


5.  Bi Samueli, Timoti 

     Lat” igba ewe won

     Ti nf’ itara sin Oluwa 

     Be l'o ye ki nma se.


6.  Ko to ki nf’ isin Oluwa 

     Se jafara rara

     Ki y’o di ola ki nto bere 

     Si ise rere yi.  Amin

English »

Update Hymn