HYMN 683

ADURA FUN AWON OBI
(FE 708) C.M.S. 397 t. H.C 34 C.M
"To omode l’ona ti yio to" - Owe 22:6



1.  OLORUN ogbon at’ore 

     Tan ‘mole at’oto

     Lati f'ona toto han wa 

     Lai to 'sise wa.


2.  Lati to wa ninu ewu

     Li arin apata

     Lati ma rin lo larin won 

     K'a m’oko wa gunle.


3.  B’or'ofe Re ti nmu wa ye 

     K’a ko won b'eko Re 

     Awa lati ko omo wa

     Ni gbogbo ona Re.


4.  Li akoko, pa ife won

     On ‘gberaga won run! 

     K'a ti ona mimo han won 

     Si Olugbala won.


5.  A fe woke nigbakugba 

     K'a to apere Re

     K‘a ru beru on ‘reti won 

     K'a tun ero won se.


6.  A fe ro won lati gbagbo 

     Ki nwon f’itara han

     Ki a mase lo ikanra 

     Gbat' a ba le lo ‘fe.


7.  Eyi l’a f'igbagbo bere 

     Ogbon t’o t'oke wa!

     K’a f’eru omo s’aiya won, 

     Pelu ife mimo.


8.  K'a so ‘fe won ti nte s’ibi 

     Kuro l'ona ewu

     K‘a fi pele te okan won 

     K'a fa won t’Olorun.  Amin

English »

Update Hymn