HYMN 681

10s (FE 706)
"Wo iya re" - John 19:27 
Tune: Wa ba mi gbe ale fere le



1.  ORUKO wo lo dun gbo bi t‘iya 

     Ti eti ngbo ti okan si bale 

     Adun t’ enu ko le so miran wo 

     Ninu oruko rere bi t’iya.


2.  A! iya ti ngba ya omo re je

     A! iya ti ngbekun omo re sun 

     A! iya ti npebi monu f’omo

    Mo fe o nigbagbogbo iya owon.


3.  Jowo ran mi Iowo, Edumare

     K'emi Ie toju awon obi mi 

     Fun mi layo pupo nigb'aiye mi 

     Ki nma sanku mo obi mi Ioju.


4.  Agborandun bi iya ko si

     Eni to ni baba Io tara re

     Bi ina ku a fi eru boju

     Iya mi ti fi mi ropo’ra re.  Amin

English »

Update Hymn