HYMN 680

C.M.S 491 H.C 495 6s 5s (FE 705) 
“Ko ju la si Esu, on o si sa kuro 
lodo nyin” - Jak. 4:7



1.  MASE huwa ese 

     Ma soro ‘binu 

     Omo Jesu l’e nse 

     Omo Oluwa.


2.  Kristi je oninure 

      At’Eni mimo

     Be l’awon omo Re 

     Ye k’o je mimo.


3.  Emi ibi kan wa 

     To nso irin re

     O si nfe dan o wo 

     Lati se ibi.


4.  E mase gbo tire 

     B‘o tile soro 

     Lati ba Esu ja 

     Lati se rere.


5.  Enyin ti se‘Ieri 

     Ni omo owo 

     Lati k’Esu sile 

     Ati ona re.


6.  Om'ogun Krist ni nyin 

     E ko lati ba

     Ese inu nyin ja

     E ma se rere.


7.  Jesu l’Oluwa nyin

     O se eni-re

     Ki enyin omo Re

     Si ma se rere.  Amin

English »

Update Hymn