HYMN 679

L.M (FE 704)
“Igberaga aso wiwo irera ati ogo asan, 
ese nla ni."



1.  K’IYA wa, Efa to d’ese 

     Tal’ o mo ohun ti nje aso?

     Ohun ta fi bo l’asiri 

     Pada d‘ohun irira re.


2.  Gbat‘ o ko gb’ewe opoto wo 

     Oso iwa mimo re lo

     Sa wo bi awa omo re

     Ti nf’ibo tiju yi sogo.


3.  Wo! b’igberaga wa ti to 

     Gbat’ a ba gb’aso titun wo 

     B’enipe awon kokoro

     At’ agutan ko ti nwo won.


4.  Wo arewa labalaba 

     Ali itanna pulpit

     B’aso mi ti wu ko po to 

     Ko t’abo ti awon wonyi.


5.  Nje ngo ma fi okan mi wa 

     Ohun oso t'oju won lo

     lwa rere at’otito

     L’oso to ju gbogb’oso lo.


6.  Nigbana l’emi y’o dara 

     Pupo j'awon kokoro lo 

     Oso awon angel l’eyi 

     Ati t‘Om‘Olorun pelu.


7.  Ki ti, ki gbo, ki sa titi 

     lpara ko si le baje

     T’ojo t’erun, bakanna ni 

     Lilo ki ba ewa re je.


8.  Eyi ngo ma wo laiye

     Ki nle ma wo l’orun pelu 

     Oso t‘o w‘Olorun l’eyi 

     Ogo ati ayo Re ni.  Amin

English »

Update Hymn