HYMN 678

ORIN ITERIBA FUN OBI
t.S.S & S. 417 (FE 703)
“Bo wo fun baba, on iya re,m ki ojo re 
ki o le pe" - Eks. 20:12
Tune: Anu Re Oluwa l’awa ntoro



1.  lYA t‘o ru mi fun osun mewa 

     Ti ko somi kale

     O bi mi tan, o tun pon mi kiri 

     F'odun meta toto.

Egbe: Iya, iya, iya, mo dupe 

          Ise re t’osan t'oru 

          Nijo jije, at'ijo alaije

          Iya nitori mi.


2.  Gba mo s’aisan tal‘o duro ti mi 

     T'o si gbe mi mora?

     Gba mo sokun, tani re mi l'ekun 

     lya, bi ko se 'wo.

Egbe: Iya, iya, iya...


3.  Nigba ewe t’emi ko le soro 

     Tani m’ohun mo fe?

     Gba mo ndagba, tani se toju mi 

     lya, iwo ha ko?

Egbe: Iya, iya, iya...


4.  Ororo oyan iya ti mo yan 

     Ko le tan lara mi

     Bi mo lowo owo mi ko le ra 

     Ise re lori mi.

Egbe: Iya, iya, iya...


5.  Enyin ore te ti so ya nyin nu 

     Mo ki nyin ku ile de

     Ati enyin t’iya nyin wa laiye 

     E f’ope f’Olorun.

Egbe: Iya, iya, iya...


6.  Je ka mura lati huwa rere 

     Bi omo ologbon

     Ka jo Jesu ninu iwa pele 

     Ka j’omo to gboran.

Egbe: Iya, iya, iya, mo dupe 

          Ise re t’osan t'oru 

          Nijo jije, at'ijo alaije

          Iya nitori mi.  Amin

English »

Update Hymn