HYMN 675

1.  AWON omode s’eka wewe 

     at’imope s'ona

     Won si nke, Hosana

     Eyi ni orin segun t’a ko wonu 

     Jerusalem

     Hosana! Hosana!

Egbe: Eyi l'Omo nla Dafidi ati Oba Israeli 

          Ogun ketekete lo fun igbala omo 

          eniyan

          Hosana! Hosana!

          Hosana si Omo Dafidi.


2.  Awon agbagba gbiyanju lati 

     pa won lenu mo

     Won tun nke Hosana

     B‘awon wonyi pa enu won mo 

     okuta yo soro

     Hosana! Hosana!

Egbe: Eyi l'Omo nla...


3.  E so fun omo binrin Sion pe 

     Oba re mbo wa

     Hosana! Hosana!

     O tenu, O si joko lori omo Ketekete 

     Hosana! Hosana!

Egbe: Eyi l'Omo nla...


4.  Olubukun I’Eni ti mbo wa l‘oruko 

     Oluwa 

     Hosana! Hosana!

     E te okan yin si ona fun Kristi

     Oba Ogo

     Hosana! Hosana!

Egbe: Eyi l'Omo nla Dafidi ati Oba Israeli 

          Ogun ketekete lo fun igbala omo 

          eniyan

          Hosana! Hosana!

          Hosana si Omo Dafidi.  Amin

English »

Update Hymn