HYMN 671

8s (FE 697)
Tune: Nigbati ldanwo yin mi ka



1.  EMI ko le gbagbe ojo 

     T‘iya so fun mi jeje, pe

     Bi o ba d’ominira tan 

     Mase gbagbe ojo iya. 

Egbe: Nigbati mo rohun gbogbo 

          lfe ti iya ni si mi

          Oro ife ran mi leti

          Pe ma gbagbe ojo iya.


2.  Emi ko le sai ma ranti 

     Gbogbo wahala iya mi 

     To ntoju mi tosan toru 

     Ninu ebi ninu ayo.

Egbe: Nigbati mo rohun...


3.  Iya wa ni onimoran 

     Baba wa ni oniranwo 

     Awon ti nse bi iya wa 

     Se won ko le jo iya wa. 

Egbe: Nigbati mo rohun...


4.  Ngo se baba, ki jo baba 

     Gba ‘po de mi, ki s’onipo 

     Sole de mi, ki s’onile 

     Alagbata s’oja d’owon. 

Egbe: Nigbati mo rohun...


5.  Enyin iya, e o jere omo 

     Enyin baba, e o jeun omo 

     Enikan ki o gba ‘se nyin se 

     Li agbara Edumare.

Egbe: Nigbati mo rohun gbogbo 

          lfe ti iya ni si mi

          Oro ife ran mi leti

          Pe ma gbagbe ojo iya.  Amin

English »

Update Hymn