HYMN 668

C.M. (FE 694)
“lfe lo ye omo enia."



1.  B’OKIKI ija tile nkan 

     T’ariwo gb’ode kan 

     K’irepo wa n’ile dara 

     Omo Iya ki ja.


2.  Awon eiye n’nu ite won 

     Ki ba ara won ja 

     Ohun itiju nla ha ko 

     K’omo-ya ka repo.


3.  Ihale-ako-apara

     Fari lasan lasan

     Kumo ni da, a fa da yo 

     A si bi ‘ku l’omo.


4.  lse bilisi n’ibinu 

     Larin omo iya 

     Ibinu ni Kaini fi Iu 

     Arakunrin re pa.


5.  Ibinu ologbon ki pe

     A tan k’orun to wo 

     Sugbon t’asiwere a wa 

     Titi d’ojo ale.


6.  Fi ese inu-bibi wa

     Ji wa, Oluwa wa

     Ka f’ibinu ewe sile 

     Ka si dagba n’ife.  Amin

English »

Update Hymn