HYMN 665

L.M. (FE 691)
“Ibura, isepe ati Ipe oruko, Olorun
lasan, ese nla ni”



1.  AWON Angeli li orun 

     Nyin O logo, Olorun wa, 

     Iwuwo opa binu Re 

     Ndamu esu l’orun egbe.


2.  Gbogbo enyin omo-komo 

     Asepe ati abura

     E se ranti ofin keta

     Ke bowo f’Oko Olorun.


3.  Nwon o se le duro, Baba 

     Niwaju agbara nla Re! 

     Awon alaiberu Olorun 

     Yio lo si orun egbe!


4.  Nibiti ki y’o si omi

     Ti y’o pa ongbe ofun won 

     Emi y’o o ma yin O titi

     Bi ngo ti ma yin li orun.


5.  lbanuje nla ni fun mi 

     Lati gbo oro buburu

     Ti awon omokomo nso 

     Si Eledumare Baba!


6.  Gbogbo won ni ngo ko l’ore

     Awon alaiberu Olorun

     Ti nwon np’oruko Re lasan

     Ti nwon mbura, ti nwon nsepe.  Amin

English »

Update Hymn