HYMN 664

C.M. (FE 690)
“Ofln enu Re dara fun mi” - Ps.119:72
Anfani isin Olorun mimo lati igba ewe.



1.  ALABUKUN FUN l’omo na 

     Lati igba ewe

     Ti ki rin l’ona iparun 

     Ti mberu Olorun.


2.  K’a fi ara wa f’Olorun 

     Lat’ igba ewe dun 

     Ebun giga n’itanna je 

     Gba to ba sese nyo.


3.  K’a t’ewe beru Oluwa 

     Rorun lopolopo

     Bi elese ti ndagba to 

     L’okan nwon si nle to.


4.  Ka gbo ti isin Olorun 

     Lati igba ewe

     N’nu ewe pupo ni a nyo 

     A si fun-ni n’ipa.


5.  Olorun Olodumare

     A f’ara wa fun O

     K'a a je tire lat’ ewe lo 

     Titi d’opin aiye.


6.  K’ise adura at’iyin

     Je ise aiye mi 

     Lojo iku, k’yio je ki nye 

     Lati f’ayo r’orun.  Amin

English »

Update Hymn