HYMN 662

S.S. 285 (FE 688)
“Oruko mi ha wa nibe" - Dan.2:1



1.  OLUWA ngo ko nani wura 

     ati fadaka

     Ngo mura lati d‘orun lati 

     wo ‘nu agbo

     Ninu iwe ijoba Re ti ewe re l’ewa,

     So fun mi Olugbala, Oko 

     mi ha wa n’ibe?

Egbe: Oko mi ha wa n’be 

           lara iwe funfun?

           So fun mi Olugbala 

           Oko mi ha wa n'be?


2.  Oluwa ese mi po bi yanrin 

     leti okun

     Sugbon eje Olugbala o to 

     lati we mi

     Nitori ileri Re ki ye lai Oluwa, 

     B’ese nyin pon bi ododo

     Yio funfun bi sno.

Egbe: Oko mi ha wa n’be...


3.  Ilu daradara ni at’ile didan Re,

     Pel’awon t’a se logo to wo 

     aso funfun

     Ohun ibi ko si mbe lati

     b’ewa re je

     Ni’b awon Angeli nso,

     Oko mi ha wa n’be. 

Egbe: Oko mi ha wa n’be 

           lara iwe funfun?

           So fun mi Olugbala 

           Oko mi ha wa n'be?  Amin

English »

Update Hymn