HYMN 660

S.492. P.M (FE 686)
“Iyawo ti Isaaki” - Gen. 25:20



1.  IYAWO ti Isaaki gbe

     Pelu Rebeka aya re

     Olorun f'ibukun fun won 

     Gege b‘igbeyawo Adam. 

Egbe: E yo, mo si tun wipe e yo - 2ce 

          E yo, e yo, e yo nin'

          Oluwa e yo.


2.  Beni ko ri fun nyin loni 

     Arakunrin, Arabinrin 

     K’ayo orun kun okan nyin 

     pelu 'bukun atoke wa.

Egbe: E yo...


3.  Ninu idamu aiye yi

     Oluwa p’awon tire mo

     Fi won si abe iso Re

     Ki nwon le bo lowo ewu.

Egbe: E yo...


4.  Enyin ore, at' ibatan 

     K’Oluwa gbo adura nyin 

     K'O f’ibukun fun nyin pelu 

     L'okunrin ati l'obinrin.

Egbe: E yo...


5.  Enyin om'Egbe Serafu 

     Ati om’Egbe Serafu 

     Ojo ayo ni eyi je 

     K’Oluwa je ki ire kari. 

Egbe: E yo...


6.  A f‘Ogo f‘Olorun baba 

     A f’Ogo f’Olorun Omo 

     A f’Ogo fun Emi Mimo 

     Metalokan Mimo lailai.

Egbe: E yo, mo si tun wipe e yo - 2ce 

          E yo, e yo, e yo nin'

          Oluwa e yo.  Amin

English »

Update Hymn