HYMN 66

O.t. H.C 152 C.M (FE 84)
"Kini ki emi ki o se lati la?" - Ise 16:30



1.  IGBALA ni, igbala ni

     Awa elese nfe

     Nitori ninu buburu

     T‘a se l‘awa nsegbe.


2.  lse owo wa ti a nse

     O nwi nigbagbogbo

     Pe, igbala ko si nibe

     Ise ko le gba ni.


3.  Awa nsebo, awa nrubo

     A nkorin, a si njo
    
    Sugbon a ko ri igbala

    Ninu gbogbo wonyi.


4.  Nibo ni igbala gbe wa?

     Fi han ni, fi han ni

     B‘o wa loke, bi isale

     B'o ba mo, wi fun wa.


5.  Jesu ni se Olugbala

     Jesu I'Oluwa wa;

     lgbala wa li owo Re

     Fun awa elese.


6.  Wa nisisyi, wa loro

     lfe wa ninu Re,

     Enyin ti o buru l’ O npe

     E wa gba igbala.  Amin

English »

Update Hymn