HYMN 658

C.M.S 504 t.H.C 564 C.M (FE 584)
"A si pe Jesu ati awon omo-ehin Re 
pelu sibi igbeyawo" - John 2:2



1.  JESU f'ara han nitoto 

     Nibi ase ‘yawo 

     Oluwa, awa be O, wa 

     F’ara Re han nihin.


2.  Fi ibukuu Re fun awon 

     Ti o dawopo yi 

     F’ojurere wo ‘dapo won 

     Si bukun egbe won.


3.  F’ebun ife kun aiya won 

     Fun won n‘itelorun

     Fi alalfia Re kun won 

     Si busi ini won.


4.  F’ife mimo so won d’okan 

     Ki nwon f 'ife kristi

     Mu aniyan ile fere

     Nipa ajumose.


5.  Jeki nwon ran ‘ra won lowo 

     Ninu ibugbe won

     Ki nwon si ni omo rere

     Ti y’o gbe ‘le won ro.  Amin

English »

Update Hymn