HYMN 657

C.M.S 503 H.C 352 
T.H.C 249 7s. 6s (FE 683)
“Olorun si sure fun won” - Gen.1:28



1.  IRE ta su ni Eden 

     N’igbeyawo kini 

     Ibukun t’a bukun won 

     O wa sibe sibe.


2.  Sibe titi di oni 

     N’igbeyawo Kristian

     Olorun wa larin wa 

     Lati sure fun wa.


3.  Ire ki nwon le ma bi

     Ki nwon ko si ma re

     Ki nwon ni ‘dapo mimo 

     T’enikan k’yo le tu.


4.  Ba ni pe, Baba, si fa 

     Obirin yi f’oko

     Bi O ti fa Baba fun Efa 

     Adam lojo kini.


5.  Ba wa pe, Immanueli 

     Si so owo won po 

     B’eda meji ti papo 

     Lara ijinle Re.


6.  Ba wa pe, Emi Mirno 

     F’ibukun re fun won 

     Si se won ni asepe 

     Gege b’O ti ma se.


7.  Fi nwon sabe abo Re 

     K’ibi kan ma ba won 

     Gba nwon npara ile Re 

     Ma toju okan won.


8.  Pelu won l’o j’aiye won 

     At’ oko at’aiya

     Titi nwon o de odo Re 

     N’ile ayo l’orun.  Amin

English »

Update Hymn