HYMN 655

t.H.C 247 7s 6s (FE 681)
“Ki Oluwa ki o sanu fun nyin ki o si 
busi fun nyin" - Ps. 67:1
Tune: Ire ta sun ni Eden



1.  BABA Olodumare 

      A ntoro anu Re 

     S’ori arakunrin 

     At'arabinrin yi.


2.  S‘Okan oko on aya 

     F'iberu Re fun won

     Ki nwon n'ife ara won 

     Ni ojo aiye won.


3.  Ran esi rere si wa 

     K’awa si le mo pe 

     Gbogbo eto oni yi 

     Je didun inu Re.


4.  Iru ojo bi on

     Jehovah Jireh wa 

     Wa lati f’ibuku fun 

     Awon enia Re.


5.  Se nwon ni abiyamo 

     Ki nwon ko si ma re 

     Eranko ati eiye 

     Nwon mbi lopolopo.


6.  F'ayo on alalfia pelu 

     Pelu itelorun

     S'ile awon omo Re 

     Pese fun aini won.


7.  Ki adun lona gbogbo 

     Yi won ka lat’ oni 

     K’ire ma ba won titi 

     K'a aiye ma le ya won.


8.  Baba Onibu-ore

     Ran ore Re si won

     Mu won bori gbogbo ota 

     Si je Olorun won.  Amin

English »

Update Hymn