HYMN 653

(FE 679)
Tune: Enyin ara n;'nu Oluwa
“Kiyesi Oko yawo mbo" - Matt. 5:2




1.  ATUPA 'wa njo, geere

     Aso wa funfun lau

     A nduro d’oko yawo, 

     a ha le wole bi? 

     A mo pe a ko ni nkan t'a 

     le pe ni tiwa 

     Ina, ororo, at’aso, t‘owo 

     Re nikan wa.

Egbe: E wo Oko yawo mbo 

          Gbogbo wa Ie wole

          T’atupa wa njo gere! 

          T'aso wa funfun lau.


2.  E jade lo pade Re, 

     lekun ti si sile

     Ogo t'o tan loju Re mu 

     gbogbo ona mole,

     Gba ipe lati wole,

     o j'ohun gbogbo lo, 

     Ma jafara! gb’atupa Re! 

     w'ayo aiyeraiye.

Egbe: E wo Oko yawo mbo...


3.  Arewa gbeyawo na, 

     b'ilekun si sibe,

     A mo p’awon t’o wole 

     d‘eni ‘bukun lailai,

     A si ri pe O wa ni ju 

     enikeni lo,

     Sugbon b’ ilekun ti, 

      lekun ki yio tun si mo Iai.

Egbe: E wo Oko yawo mbo 

          Gbogbo wa Ie wole

          T’atupa wa njo gere! 

          T'aso wa funfun lau.  Amin

English »

Update Hymn