HYMN 65

(FE 33)
"Wa si orisun na" - Ps. 36:9



1.  ELESE wa s'orisun na,

     Wa pelu 'banuje re,

     Ri won sinu omi jijin

     'Wo y‘o r'irorun nibe

Egbe:  Yara kalo, mase duro

           lseju kan le so emi re nu

           Jesu nduro Iati gba o,

           Anu mbe fun o loni.


2.  Wa t’iwo t’eru ese re

     Jesu ti nduro de o,

     B’ese re pon bi alari,

     Nwon yio funfun bi sno.

Egbe:  Yara kalo, mase duro...


3.  Jesu olugbala wipe,

     Awon ti o ba gbagbo

    Ti nwon si ronupiwada

    Y’o r’iye gba lodo re.

Egbe:  Yara kalo, mase duro...


4.  Wa we ninu orisun na,

     F‘eti si ohun ife

     Jeki awon Angeli yio

     F’elese to yi pada.

Egbe:  Yara kalo, mase duro...  Amin

English »

Update Hymn