HYMN 648

H.C 441 10s (FE 674)
"Ara mi ti a fi fun nyin Ii eyi, e ma
se eyi ni iranti mi" - Luku 22:19


1.  SUNMOHIN, k’o gba Ara Oluwa 

     K’o mu Eje mimo t’a ta fun o.


2.  Ara at’eje na l'o gba la

     N’itura okan, f'ope f’Olorun.


3.  Elebun igbala, Omo Baba 

     Agbelebu Re fun wa n'isegun.


4.  A fi On rubo fun tagba tewe 

     On tikare l‘Ebo, On l’Alufa.


5.  Gbogb’ ebo awon Ju laiye ‘gbani 

     J‘apere ti nso t’Ebo yanu yi.


6.  On I’Oludande, On ni Imole 

     On nf‘Emi ran awon Tire lowo.


7.  Nje, e f’okan igbagbo sunmo‘ hin 

     Ki e si gba eri igbala yi.


8.  On l'o nsakoso enia Re Iaiye 

     On l‘o nf’iye ainipekun fun wa.


9.  On f’onje orun f’awon t’ebi npa 

     Omi iye fun okan ti npongbe.


10.  Onidajo wa, Olugbala wa

       Pelu wa ni ase ife re yi.  Amin

English »

Update Hymn