HYMN 647

o.T. 264 8.7 (FE 673)
Tune: Emi ti o nji oku dide



1.  OLUGBALA a de loni 

     Lati wa da Majemu 

     Ran Emi Iye Re si wa 

     K’O so gbogbo wa dotun. 

Egbe:  Emi Mimo sokale wa 

            Wa fi agbara Re han 

            Olugbala, Olugbala 

            Olugbala, ba wa pe.


2.  Wa tun ‘baje inu wa se 

     F’ara re han wa loni 

     Ma je ki Esu ba wa pe 

     Ran Emi Re si arin wa. 

Egbe:  Emi Mimo...


3.  Emi Agbara sokale 

     F’owo ife yi wa ka 

     Ka simi le ileri Re 

     Ka mase siyemeji.

Egbe:  Emi Mimo...


4.  Ma je ki ife wa tutu 

     Larin Egbe Mimo yi 

     Ka le fa opo agutan 

     Si ‘nu agbo Mimo yi. 

Egbe:  Emi Mimo...


5.  Baba wa gbo tiwa loni 

     Sokale nin‘ola Re 

     Lati wa ya wa si mimo 

     K'Emi Mimo ba le wa.

Egbe:  Emi Mimo...


6.  E f’Ogo fun Baba l’oke 

     E f’ogo fun Omo Re 

     Ogo ni fun Emi Mimo 

     Ogo fun Metalokan.

Egbe:  Emi Mimo sokale wa 

            Wa fi agbara Re han 

            Olugbala, Olugbala 

            Olugbala, ba wa pe.  Amin

English »

Update Hymn