HYMN 636

(FE 662)



1.  MO layo pe Baba wa li orun 

     F'ife Re han ninu iwe li orun 

     Mo r'ohun ‘yanu ninu Bibeli 

     Ife Jesu si mi b’o ti po to.

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi 

           Jesu fe mi, Jesu fe mi 

           Mo Iayo wipe Jesu fe mi 

           Jesu fe an'emi.


2.  Mo gbagbe Re, mo si sako kuro 

     Sibe o fe mi, bi mo ti nsako

     Mo fo pada s’abe apa ‘fe Re 

     Gbati mo ranti pe Jesu fe mi. 

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi...


3.  B‘o je pe orin kan ni mo le ko

     Ninu ewa ni mo r‘Oba Nla ni 

     Eyi ni y’o j'orin mi tit‘aye 

     Iyanu lo je pe Jesu fe mi.

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi...


4.  Jesu fe mi, mo mo pe, emi fe E 

     lfe lo mu wa lati gba mi la 

     N'ife l’O ku lori agbelebu

     O da mi loju pe Jesu fe mi. 

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi...


5.  B’a bi mi lere, kini esi mi? 

     Ogo fun Jesu, eyi si daju

     Erni mimo pelu mi si gbagbo

     Lati jeri wipe Jesu fe mi. 

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi...


6.  Eyi daju pe, mo ni isimi

     A bukun mi pe mo gba Jesu gbo

     A gb’okan mi la, Esu sa fun mi

     Gbati mo so fun u pe Jesu fe mi.

Egbe:  Mo layo wipe Jesu fe mi 

           Jesu fe mi, Jesu fe mi 

           Mo Iayo wipe Jesu fe mi 

           Jesu fe an'emi.  Amin

English »

Update Hymn