HYMN 631

C.M.S 498 H.C 516 7s (FE 657) 
"Bi enikeni ba nsin, mi ki o ma to
Mi lehin” - John 12:26 



1.  MO ti seleri Jesu

     Lati sin O dopin 

     Ma wa lodo mi titi 

     Baba mi, Ore mi

     Emi k’yo beru ogun 

     B’lwo ba sunmo mi 

     Emi ki y'o si sina 

     B’O ba f’ona han mi.


2.  Je ki nmo p’O sunmo mi 

     Tori ibaje aiye

     Aiye fe gba okan mi 

     Aiye fe tan mi je 

     Ota yi mi ka kiri

     Lode ati ninu

     Sugbon Jesu, sunmon mi 

     Dabobo okan mi.


3.  Je ki emi k’o ma gbo 

     Ohun Re, Jesu mi 

     Ninu igbi aiye yi

     Titi nigbagbogbo 

     Ko, mu k’o dami l’oju 

     K’okan mi ni janu

     Ko, si mu mi gboTire 

     Wo Olutoju mi.


4.  Wo ti seleri, Jesu 

     F’awon t’o tele O 

     Pe ibikibi ti O wa 

     L’awon yio si wa 

     Mo ti seleri, Jesu 

     Latin sin O dopin 

     Jeki nma to O lehin 

     Baba mi, Ore mi.


5.  Jeki nma ri pase Re 

     Ki nle ma tele O 

     Agbara Re nikan ni

     Ti mba le tele O 

     To mi, pe mi, si fa mi

     Di mi mu de opin

     Si gba mi si odo Re 

     Baba mi, Ore mi.  Amin

English »

Update Hymn