HYMN 627

H.C 509 P.M (FE 653)
“Okan mi nto O lehin girigiri”
- Ps. 63:8



1.  L’EKAN mo jina s’Oluwa 

     Mo nfi iwa mi bi ninu 

     Sugbon Jesu ti gba mi, 

     Halleluya.


Chorus:  A, bi o ti dun to

              Dun to, dun to dun to 

              A, bi o ti dun to

              Ki Jesu ma gbe inu mi.


2.  Ibinu ati runu mi

     Ewon ti Esu fi de mi

     Jesu ti da ide na 

     Halleluya.

Chorus:  A, bi o ti dun to, - 3ce...


3.  Ifekufe kun okan mi

     Pelu igberaga gbogbo 

     In’Emi ti jo won

     Halleluya.

Chorus:  A!, bi o ti dun to, - 3ce...


4.  Mo bo lowo irewesi, 

     Lowo ko gbona ko tutu, 

     E ba mi yin Oluwa 

     Halleluya.

Chorus:  A!, bi o ti dun to, - 3ce...


5.  Mo nkorin si lojojumo

     Mo nyo mo si tun nfo s’oke

     Nipa gbara Emi

     Halleluya.

Chorus:  A!, bi o ti dun to, - 3ce...


6.  Eje yebiye we mi mo 

     Omi iye nsan ninu mi

     Igbala mi di kikun

     Halleluya.

Chorus:  A!, bi o ti dun to, - 3ce...


7.  Enyin ara at’ore mi 

     Tani ko fe ri igbala

     Ofe ni l’odo Jesu

     Halleluya.

Chorus:  A, bi o ti dun to

              Dun to, dun to dun to 

              A, bi o ti dun to

              Ki Jesu ma gbe inu mi.  Amin

English »

Update Hymn