HYMN 626

11s (FE 652)
"Awon ti o gbekele Oluwa yio dabi 
Oke Sioni ti a ko le si ni di" - Ps.125:1
Tune: E ma tesi waju Serafu Mimo



1.  NI INU airiji re gbekele Jesu

     Ni inu hila-hilo aiye, gbekele Jesu 

     Mase gbekele enia, sugbon gbekele Jesu, 

     On nikan lo le gba o, sa gbeke re le.

Egbe:  Enit’ o npese fun era 

           On na ko le bo o ti 

           Bi o ti wu k'o le to

           Gbekele Jesu.


2.  Enyin Om'Ogun ‘gbala yi gbekele Jesu 

     E ke Hosanna f’Oba omo ninu Dafidi 

     Enit’O ni kokoro iku ati iye lowo 

     On nikan lo le gba o sa ma se ‘fe Re.

Egbe:  Enit’ o npese fun era...


3.  Enyin Leader wa owon, E ku se Emi 

     Jah yio so ile ati ona nyin, 

     Sa ma s’otito

     Jeki iwa rere nyin han

     Fun gbogbo awon eda 

     Ogun orun yio jeri nyin 

     enyin o gb’ade ade ogo.

Egbe:  Enit’ o npese fun era...


4.  Enyin Egbe Aladura 

     e ma bohun mo

     Sise nigbati nse osan 

     nitori oru mbo

     Gbe ida ‘segun re s'oke, e

     mase b’oju w‘ehin

     Ma gbeke re le enia, teju mo Iesu.

Egbe:  Enit’ o npese fun era...


5.  Enyin omo Egbe Akorin

     E tun ohun nyin se

     Orin l'e o ma ko titi n‘ile 

     Baba orun 

     Jesu yio mu nyin de’le lo si 

     ilu mimo l’oke

     Lati pelu ogun orun ti 

     nyins Od’agutan.

Egbe:  Enit’ o npese fun era...


6.  Enyin Om’Egbe Serafu ati Kerubu 

     Emi Mimo yio ma so nyin ma 

     beru ota

     Agbara tit’ oke wa orin

     segun l’ ao ma ko,

     Ogo fun Baba, Omo ati Emi Mimo.

Egbe:  Enit’ o npese fun era 

           On na ko le bo o ti 

           Bi o ti wu k'o le to

           Gbekele Jesu.  Amin

English »

Update Hymn