HYMN 625

H.C 294 6.Ss (FE 651) 
"Emi se ara mi bi enipe tabi 
arakunrin" - Ps. 35:14



1.  ORE aiye ki lo jamo 

     Ohun asan ni mo mo si 

     Ko si alanu bi Jesu,

     Alawoko, Olorun ni 

     Adawunse ko, Olorun ni 

     Enia ko, Olorun ni.


2.  O ye ki nfi Jesu s’ore 

     Ko si ore kan bi Jesu 

     Jesu to fe wa d’oju ku

     Babalawo ko Olorun ni 

     Awole ko, Olorun ni 

     Enia ko, Olorun ni.


3.  Nko ni eniti mba kepe 
 
     Mo wo waju mo wo ehin 

     Ko tile si alabaro

     Onisegun ko, Olorun ni 

     Awole ko Olorun ni 

     Enia ko, Olorun ni.


4.  Sugbon mo ro mo O, Jesu 

     Emi ki yio fi O sile

     Jesu ma sai ran mi lowo

     Alawo ko, Olorun ni 

     Enia ko, Olorun ni 

     Akunleyan lo mba mi ja.


5.  Gbati mo joko n’ile mi 

     Esu wa d’eru b’okan mi 

     Sugbon Jesu gbemi leke

     Nwon ni mo ku l’araiye so 

     Nwon l’o ti ku l’araiye so 

     Sugbon Jesu da mi sile.


6.  Alairise, ko ma binu 

     Alaisan ma so ‘reti nu 

     Jesu yio mu nyin lara da

     Alawo ko, Olorun ni 

     On’segun ko, Olorun ni 

     Enia ko, Olorun ni.


7.  K’a f’ogo fun Baba l’oke 

     K’a f'ogo fun Omo pelu 

     Ogo ni fun Metalokan

     Olosanyin ko, Olorun ni 

     Aworawo ko, Olorun ni 

     Jesu nikan lo to kepe.  Amin

English »

Update Hymn