HYMN 623

C.M.S 500 H.C 449 2nd Ed t.S.65 
P.M (FE 649)
"Okan mi ti mura, Olorun, okan 
mi ti mura" - Ps. 57:7



1.  OJO nla l’ojo ti mo yan 

     Olugbala l‘olorun mi

     O ye ki okan mi ma yo 

     Ko si ihin na kale.

Egbe:  Ojo nla I’ojo na!

           Ti Jesu we ese mi nu

           O ko mi ki nma gbadura 

           Ki nma sora, ki nsi ma yo 

          Ojo nla I'ojo na! 

          Ti Jesu we ese mi nu.


2.  Ise igbala pari na

     Mo di t’Oluwa mi loni 

     On l'o pe mi ti mo si je 

     Mo f’ayo j’ipe mimo na 

Egbe:  Ojo nla I’ojo na...


3.  Eje mimo yi ni mo je 

     F‘Eni to ye lati feran 

     Jek’orin didun kun ‘le Re 

     Nigba mo ba nlo sin nibe.

Egbe:  Ojo nla I’ojo na...


4.  Simi aiduro okan mi 

     Simi le Jesu Oluwa 

     Tani je wipe aiye dun 

     Ju odo awon Angeli. 

Egbe:  Ojo nla I’ojo na...


5.  Enyin orun, gbo eje mi 

     Eje mi ni ojojumo 

     Em‘o ma so d’otun titi 

     lku y‘o fi mu mi re le.

Egbe:  Ojo nla I’ojo na!

           Ti Jesu we ese mi nu

           O ko mi ki nma gbadura 

           Ki nma sora, ki nsi ma yo 

          Ojo nla I'ojo na! 

          Ti Jesu we ese mi nu.  Amen

English »

Update Hymn