HYMN 619

C.M.S 448 t.H.C 34 C.M (FE 645) 
“Eje Jesu Kristi omo re ni nwe wa 
nu kuro ninu ese wa gbogbo" - 1Joh. 1:7



1.  NIHINYI n’isimi gbe wa 

     Niha re ti eje nsan

     Eyi nikan n’ireti mi

     Pe Jesu ku fun mi.


2.  Olugbala Olorun mi 

     Orisun f‘ese mi

     Ma f‘eje re won mi titi 

     K’emi le di mimo.


3.  We mi, si se mi ni Tire 

     We mi, si je temi

     We mi, ki s‘ese mi nikan 

     Owo at’okan mi.


4.  Ma sise lokan mi, Jesu 

     Titi gbagbo y'o pin

     Tit’ ireti y‘o fi dopin 

     T'okan mi yio Simi.  Amin

English »

Update Hymn