HYMN 616

(FE 642)
"Adaba mimo si ba le ori 
re" - Matt. 3:16



1.  JESU nlo sinu odo Jordan - 3ce 

     Lodo Johanu Baptist.

Egbe:  A nlo sodo Jordan

           Pelu Olugbala wa

           A nlo soda Jordan! 

           Odo iwenumo.


2.  Ka to le d’ade, a o ma korin - 3ce

     Orin ife mimo.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


3.  Jesu yio gbade f'omo Re - 3ce

     F'awon ayanfe Re.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


4.  Adaba, mimo sokale - 3ce

     S'or'Olugbala wa.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


5.  A gbohun kan lat'orun wa - 3ce

     Eyi l'ayanfe Mi.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


6.  Ema gbo Tire titi aiye, - 3ce

     Odo Iwenumo.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


7.  Jesu Oluwa ti d'odo na - 3ce

     Odo Iwenumo.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


8.  Gbogbo elese e wa kalo - 3ce

     Sinu odo Jordan.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


9.  Kerub' Serafu e wa kalo - 3ce

     Sod' Olugbala wa.

Egbe:  A nlo sodo Jordan...


10.  Ade iye yio je ti wa - 3ce 

       Bi a ba gba Jesu gbo.

Egbe:  A nlo sodo Jordan

           Pelu Olugbala wa

           A nlo soda Jordan! 

           Odo iwenumo.  Amin

English »

Update Hymn