HYMN 615

S.S 366 (FE 641)
“A ko le ma sai tun nhyin bi” 
- John 3:7



1.  IJOYE kan to Jesu lo l'oru

     O mbere ona ‘mole on igbala 

     Olukoni f‘esi to yanju pe

     Ki a sa tun yin bi.

Egbe:  Ki a sa tun yin bi - 2ce

            Lotito, lotito ni mo wi fun o 

            Ki a sa tun nyin bi.


2.  Enyin om’araiye sami soro na 

     Ti Jesu Oluwa fara bale so 

     Mase jek‘iko yi si o j’asan

     Ki a sa tun nyin bi.

Egbe:  Ki a sa tun yin bi...


3.  Enyin to fe wo ‘simi to l’ogo yi 

     Te nfe b'enirapada korin bukun 

     Bi e ba nfe gba iye ainipekun

     Ki a sa tun nyin bi. 

Egbe:  Ki a sa tun yin bi...


4.  O nfe r‘olufe kan t’o ti lo bi? 

     Lenu lekun dada to ti nsona fun o

     Nje teti s'egbe orin didun yi pe

     Ki a sa tun nyin bi.

Egbe:  Ki a sa tun yin bi - 2ce

            Lotito, lotito ni mo wi fun o 

            Ki a sa tun nyin bi.  Amin

English »

Update Hymn