HYMN 614

H.C 218 t..C 96. D.7s 7s (FE 640)
"Ohun eniti nkigbe ni iju” - Isa.40:3



1.  OHUN ti ndun l'aginju 

     Ohun alore ni 

     Gbo b‘o ti ndun rara pe 

     E ronupiwada!

     Ohun na ko ha dun to? 

     Ipe na ko kan o!

     Kil’ o se arakunrin 

     Ti o ko fi mira?


2.  Ijoba ku si dede 

     Ijoba Olorun

     Awon t'o ti fo so won 

     Nikan ni yio gunwa 

     Ese t’o ko fi nani 

     Ohun alore yi

     Ti dun l'eti re tantan 

     Pe ronupiwada.


3.  Abana pelu Fapar 

     Le je odo mimo 

     Sugbon ase wenumo 

     Jordan nikan l’o ni 

     Ju ero re s’apakan 

     Se ase Oluwa

     Wa s’inu adagun yi 

     We k’o si di mimo.


4.  Kin’ iba da o duro? 

     Awawi kan ko si

     Wo odo, wo Johanu re 

     Ohun gbogbo setan

     O pe ti o ti njiyan

     O ha bu Emi ku? 

     Elese gbo alore

     Si ronupiwada.  Amin

English »

Update Hymn