HYMN 612

(FE 638)



1.  OHUN aiye b’aiye lo 

     Kerubu, Serafu

     Ilu ti a te sori oke

     A ko le fara sin.

Egbe: Je ka soto - (3) 

           Ka le ri gbala 

           nikehin.


2.  Ohun aiye b’aiye lo 

     E ranti ti aya Loti 

     Ti o boju wo ehin 

     Ti o fi di owon iyo.

Egbe: Je ka soto...


3.  Ohun aiye b’aiye lo 

     E ranti ojo Mose

     Ti Farao fi ri s’okun 

     Ti Israel fi ri igbala.

Egbe: Je ka soto...


4.  Ohun aiye b’aiye lo 

     E ranti ojo Noah 

     T’omo enia fi npegan 

     Ti eranko fi ri igbala.

Egbe: Je ka soto...


5.  Enyin Egbe Oloye 

     At’enyin egbe Mary 

     Baba yio wa pelu nyin 

     Yio di nyin lamure ododo.

Egbe: Je ka soto...


6.  Enyin Egbe Martha 

     Ati Ayaba Esther

     E mura lati sise nyin 

     Baba yio se iranwo.

Egbe: Je ka soto...


7.  Enyin Egbe Akorin 

      Ati ‘Tan-lehin Jesu 

     E mura lati sise nyin 

     Jesu yio se iranwo.

Egbe: Je ka soto...


8.  Mose Orimolade

     O ti lo soke orun

     O dapo mo awon Angel 

     O ti gbade Ogo.

Egbe: Je ka soto...


9.  Enyin Egb’Aladura

     E ku aseyinde

     Baba yio tu nyin ninu 

     Yio gb’owo nyin soke.

Egbe: Je ka soto...


10.  Ogo ni fun Baba wa 

       Ogo ni fun Omo Re 

       Ogo ni fun Emi Mimo 

       Metalokan lailai.

Egbe: Je ka soto - (3) 

           Ka le ri gbala 

           nikehin.  Amin

English »

Update Hymn