HYMN 61

7s 6s (FE 78)
Tune: Duro, Duro fun Jesu.



1.  BABA WA ti mbe l'orun

     Owo loruko Re,

     Ife tire ni ka se

     Bi nwon ti nse lorun

     Fun wa l'onje ojo wa

     ‘Dari ese ji wa,

     Gba wa lowo idanwo

     Gba wa lowo ewu.


2.  Iwo to gbo t'Elija

     Leba odo Kedron

     lwo to gbo ti Daniel

     Ko gbo ti wa loni,

     Fun wa niru agbara

     To fi f'awon Apostle

     K'awa le wulo fun O

     Ka jere bi ti won.


3.  Fun wa lokan igbagbo

     Ti ki y’o ye lailai

     Ka gbekele O titi,

     Ao fi r’ oju Re,

     Je ka le ni ireti

     Ninu Iwo nikan

     Ka nife s’enikeji,

     Ka si n’iwa pele.


4.  Baba a si tun mbe O,

     Ani fun OIon' wa,

     Ko fi Emi meje Re

     Se ‘tura f ’okan re,

    Je ki awa le ma rin

    Lona to nto wa si

    Ko le ko wa de Canaan

    Niwaju Ite re.


5.  Iwo to gbo ti Sedrak,

     Mesak, Abednego

     Gbo t’awa Egbe Serafi,

     Gbat’a ba nkepe O

     Fi agbara Re wo wa

     Bi ti woli isaju

     Ka ni ‘gboya bi ti won

     Ka segun aiye yi.


6.  Awon Omo Isreal,

     Ninu rin ajo won,

     Iwo lo ns’amona won,

     Ati abo fun won,

     Bi nwon ti ndese si O,

     Be lo ndariji won,

     Jowo ko dariji wa,

     Awa Egbe Serafu.


7.  Olorun Abrahamu,

     Olorun Isaaki

     Ati Olorun Jakobu

     Awa f’ope fun O

    Ogo, iyin, olanla

    S'Eni Metalokan

    Halleluyah’s Olorun

    Aiye ainipekun.  Amin

English »

Update Hymn