HYMN 604

C.M.S 406 t. H.C 18 C.M (FE 630)
'Gbogbo eniti ongbe ngbe, e wa sibi 
omi" - Isa. 55:1



1.  ENYIN t’ongbe ngbe e wa mu

     Omi iye ti nsan

     Lati orisun ti Jesu

     Lai sanwo l’awa mbu.


2.  Wo! b’o ti pe to t'e ti nmu

     Ninu nkan eke

     T'e nl'agbara at’ogun nyin

     Ninu nkan t'o nsegbe.


3.  Jesu wipe, isura mi

     Ko lopin titi lai

     Yio f ‘ilera lailai fun

     Awon t'o gbo Tire.  Amin

English »

Update Hymn