HYMN 600

110 8s 7s (FE 626)
“Ke rara, mase dasi, gbe ohun 
Re soke bi ipe" - Isa. 58:1




1.  ENYIN enia Olorun 

     Okunkun yi aiye ka 

     So hun ayo ti Jesu 

     Ni gbogb’ orile ede.

Egbe: Ihin ayo, Ihin ayo 

          Ti ‘toye Olugbala.


2.  Ma tiju ihinrere Re, 

     Agbara Olorun ni

     N’ilu t’a ko wasu Jesu 

     Kede dasile f’onde.

Egbe: Idasile, ldasile

          Bi t’awon Omo Sion.


3.  B’aiye on Esu dimolu 

     S‘ise Olugbala wa,

     Ja fun ise Re, ma f’oiya 

     Mase beru enia.

Egbe: Nwon nse lasan, nwon 

          nse lasan,

          lse Re ko le baje.


4.  Gbati ewu nla ba de si nyin 

     Jesu y‘o dabobo nyin 

     Larin ota at’alejo 

     Jesu y‘o je Ore nyin.

Egbe: ltoju Re, Itoju Re

           Y'o pelu nyin tit’t opin.  Amin

English »

Update Hymn